Nitori pe ṣãju ọjọ wọnni ọya enia kò to nkan, bẹni ọ̀ya ẹran pẹlu; bẹ̃ni kò si alafia fun ẹniti njade lọ, tabi ẹniti nwọle bọ̀, nitori ipọnju na: nitori mo doju gbogbo enia olukuluku kọ aladugbo rẹ̀.