13. Ọmọ mi, jẹ oyin, nitoriti o dara; ati afara oyin, ti o dùn li ẹnu rẹ:
14. Bẹ̃ni ìmọ ọgbọ́n yio ri si ọkàn rẹ: bi iwọ ba ri i, nigbana ni ère yio wà, a kì yio si ke ireti rẹ kuro.
15. Máṣe ba ni ibuba bi enia buburu, lati gba ibujoko olododo: máṣe fi ibi isimi rẹ̀ ṣe ijẹ.
16. Nitoripe olõtọ a ṣubu nigba meje, a si tun dide: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu sinu ibi.
17. Máṣe yọ̀ nigbati ọta rẹ ba ṣubu, má si ṣe jẹ ki inu rẹ ki o dùn nigbati o ba kọsẹ̀:
18. Ki Oluwa ki o má ba ri i, ki o si buru li oju rẹ̀, on a si yi ibinu rẹ̀ pada kuro lori rẹ̀.
19. Máṣe ilara si awọn enia buburu, má si ṣe jowu enia buburu.
20. Nitoripe, ère kì yio si fun enia ibi; fitila enia buburu li a o pa.
21. Ọmọ mi, iwọ bẹ̀ru Oluwa ati ọba: ki iwọ ki o má si ṣe dàpọ mọ awọn ti nṣe ayidayida.