5. Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran?
6. Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ?
7. Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ.
8. Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were.
9. Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa.
10. Ãnu ati otitọ padera; ododo ati alafia ti fi ẹnu kò ara wọn li ẹnu.
11. Otitọ yio rú jade lati ilẹ wá: ododo yio si bojuwò ilẹ lati ọrun wá.
12. Nitõtọ Oluwa yio funni li eyi ti o dara; ilẹ wa yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá.
13. Ododo yio ṣãju rẹ̀; yio si fi ipasẹ rẹ̀ ṣe ọ̀na.