15. Bi ẹnyin ba si gàn ìlana mi, tabi bi ọkàn nyin ba korira idajọ mi, tobẹ̃ ti ẹnyin ki yio fi ṣe gbogbo ofin mi, ṣugbọn ti ẹnyin dà majẹmu mi;
16. Emi pẹlu yio si ṣe eyi si nyin; emi o tilẹ rán ẹ̀ru si nyin, àrun-igbẹ ati òjojo gbigbona, ti yio ma jẹ oju run, ti yio si ma mú ibinujẹ ọkàn wá: ẹnyin o si fun irugbìn nyin lasan, nitoripe awọn ọtá nyin ni yio jẹ ẹ.
17. Emi o si kọ oju mi si nyin, a o si pa nyin niwaju awọn ọtá nyin: awọn ti o korira nyin ni yio si ma ṣe olori nyin; ẹnyin o si ma sá nigbati ẹnikan kò lé nyin.
18. Ninu gbogbo eyi, bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, nigbana li emi o jẹ nyin ni ìya ni ìgba meje si i nitori ẹ̀ṣẹ nyin.
19. Emi o si ṣẹ́ igberaga agbara nyin; emi o si sọ ọrun nyin dabi irin, ati ilẹ nyin dabi idẹ: