Nitorina gbọ́ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀bẹ mi, emi bẹ̀ ọ, ki o wá si iwaju rẹ; ki iwọ ki o má jẹ ki emi pada si ile Jonatani akọwe, ki emi má ba kú nibẹ.