Nitorina ni ibinu Oluwa fi ràn si enia rẹ̀, o si ti na ọwọ́ rẹ̀ si wọn, o si ti lù wọn: awọn òke si warìri, okú wọn si wà bi igbẹ li ãrin igboro. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.