AWỌN olugbe Jerusalemu, si fi Ahasiah, ọmọ rẹ̀ abikẹhin, jọba ni ipò rẹ̀: nitori awọn ẹgbẹ́ ogun, ti o ba awọn ara Arabia wá ibudo, ti pa gbogbo awọn ẹgbọn. Bẹ̃ni Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, jọba.