11. Pẹlupẹlu, baba mi, wõ, ani wo eti aṣọ rẹ li ọwọ́ mi; nitori emi ke eti aṣọ rẹ, emi ko si pa ọ, si wò, ki o si mọ̀ pe, kò si ibi tabi ẹ̀ṣẹ li ọwọ́ mi, emi kò si ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ ndọdẹ ẹmi mi lati gba a.
12. Ki Oluwa ki o ṣe idajọ larin emi ati iwọ, ati ki Oluwa ki o gbẹsan mi lara rẹ; ṣugbọn ọwọ́ mi ki yio si lara rẹ.
13. Gẹgẹ bi owe igba atijọ ti wi, Ìwabuburu a ma ti ọdọ awọn enia buburu jade wá; ṣugbọn ọwọ́ mi kì yio si lara rẹ.
14. Nitori tani ọba Israeli fi jade? tani iwọ nlepa? okú aja, tabi eṣinṣin?
15. Ki Oluwa ki o ṣe onidajọ, ki o si dajọ larin emi ati iwọ, ki o si wò ki o gbejà mi, ki o si gbà mi kuro li ọwọ́ rẹ.
16. O si ṣe, nigbati Dafidi si dakẹ ọ̀rọ wọnyi isọ fun Saulu, Saulu si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Saulu si gbe ohùn rẹ̀ soke, o sọkun.
17. O si wi fun Dafidi pe, Iwọ ṣe olododo jù mi lọ: nitoripe iwọ ti fi ire san fun mi, emi fi ibi san fun ọ.
18. Iwọ si fi ore ti iwọ ti ṣe fun mi hàn loni: nigbati o jẹ pe, Oluwa ti fi emi le ọ li ọwọ́, iwọ kò si pa mi.