Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi, nitoriti baba rẹ̀ ṣe ore fun mi. Dafidi si ran onṣẹ lati tù u ninu nitori baba rẹ̀. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Dafidi wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni, si ọdọ Hanuni lati tù u ninu.