1. LI ọdun kẹta ijọba Belṣassari ọba, iran kan fi ara hàn fun mi, ani emi Danieli, lẹhin iran ti emi ri ni iṣaju.
2. Emi si ri loju iran, o si ṣe nigbati mo ri, ti mo si wà ni Ṣuṣani, li ãfin, ti o wà ni igberiko Elamu, mo si ri loju iran, mo si wà leti odò Ulai.
3. Mo si gbé oju mi soke, mo si ri, si kiye si i, àgbo kan ti o ni iwo meji duro lẹba odò na: iwo mejeji na si ga, ṣugbọn ekini ga jù ekeji lọ, eyiti o ga jù li o jade kẹhin.
4. Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla.
5. Bi mo si ti nwoye, kiyesi i, obukọ kan ti iha iwọ-õrùn jade wá sori gbogbo aiye, kò si fi ẹsẹ kan ilẹ: obukọ na si ni iwo nla kan lãrin oju rẹ̀.
6. O si tọ̀ àgbo ti o ni iwo meji na wá, eyi ti mo ti ri ti o duro lẹba odò na, o si fi irunu agbara sare si i.
7. Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀.
8. Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun.