8. “Nítorí náà, sọ fún Dafidi iranṣẹ mi pé, ‘Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo mú un kúrò níbi tí ó ti ń ṣọ́ àwọn aguntan, ninu pápá, mo sì fi jọba Israẹli, àwọn eniyan mi.
9. Mo wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó lọ, mo sì ń ṣẹgun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ fún un, bí ó ti ń tẹ̀síwájú. N óo sọ ọ́ di olókìkí bí ọba tí ó lágbára jùlọ láyé.
10. N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo sì fìdí wọn múlẹ̀ níbẹ̀. Wọn yóo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò sì ní ni wọ́n lára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ibi kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́