5. Rutu bá dá Naomi lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni n óo ṣe.”
6. Rutu bá lọ sí ibi ìpakà, ó ṣe bí ìyá ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un.
7. Nígbà tí Boasi jẹ, tí ó mu tán, tí inú rẹ̀ sì dùn, ó lọ sùn lẹ́yìn òkítì ọkà Baali tí wọ́n ti pa. Rutu bá rọra lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sùn tì í.
8. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, Boasi tají lójijì, bí ó ti yí ara pada, ó rí i pé obinrin kan sùn ní ibi ẹsẹ̀ òun.
9. Ó bá bèèrè, pé, “Ìwọ ta ni?”Rutu dáhùn, ó ní, “Èmi Rutu, iranṣẹbinrin rẹ ni. Da aṣọ rẹ bo èmi iranṣẹbinrin rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ mi jùlọ.”
10. Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka.