16. Ó nawọ́ láti òkè wá, ó sì dì mí mú,ó fà mí jáde láti inú ibú omi.
17. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi tí ó lágbára,ati lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi;nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.
18. Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi,ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi.
19. Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè,ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi.
20. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè.