Onani dá Dafidi lóhùn pé, “olúwa mi, mú gbogbo rẹ̀, kí o sì ṣe ohun tí o bá fẹ́ níbẹ̀. Wò ó, mo tún fún ọ ní àwọn akọ mààlúù yìí fún ẹbọ sísun, ati pákó ìpakà fún dídá iná ẹbọ sísun, ati ọkà fún ẹbọ ohun jíjẹ. Mo bùn ọ́ ní gbogbo rẹ̀.”