àìsàn burúkú ni yóo pa wọ́n. Ẹnìkan kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin wọ́n; bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọn yóo rí lórí ilẹ̀. Ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n run, òkú wọn yóo sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.