7. Ìwà ipá àwọn ẹni ibi ni yóo gbá wọn dànù,nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe òtítọ́.
8. Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,ṣugbọn ìrìn aláìlẹ́bi a máa tọ́.
9. Ó sàn láti máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.
10. Ibi ni ọkàn eniyan burúkú máa ń fẹ́,àwọn aládùúgbò rẹ̀ kì í sìí rí ojurere rẹ̀.
11. Ìjìyà ẹlẹ́yà a máa mú kí òpè gbọ́n,tí a bá ń kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo ní ìmọ̀ sí i.
12. Olódodo ṣàkíyèsí ilé eniyan burúkú,eniyan burúkú sì bọ́ sinu ìparun.