25. OLUWA a máa wó ilé agbéraga,ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.
26. Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA,ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.
27. Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn,ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè.
28. Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.