16. Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA,ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.
17. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́,sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.
18. Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè,ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.
19. Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ,ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.
20. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.
21. Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n,ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.
22. Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú,ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.