N óo gbé ọ jù sinu aṣálẹ̀, ìwọ ati gbogbo ẹja inú odò Naili rẹ. Ẹ ó bọ́ lulẹ̀ ninu pápá tí ó tẹ́jú. Ẹnìkan kò sì ní kó òkú yín jọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin yín. Mo ti fi yín ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ.