26. Ẹyọ oyún kan kò ní bàjẹ́ lára àwọn obinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ obinrin kan kò ní yàgàn ninu gbogbo ilẹ̀ yín. N óo jẹ́ kí ẹ gbó, kí ẹ sì tọ́.
27. “N óo da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń lọ dojú ìjà kọ, rúdurùdu yóo sì bẹ́ sí ààrin wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa sálọ, nígbàkúùgbà tí wọ́n bá gbúròó yín.
28. N óo rán àwọn agbọ́n ńlá ṣáájú yín, tí yóo lé àwọn ará Hifi ati àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti jáde fún yín.
29. N kò ní tíì lé wọn jáde fún ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má baà di aṣálẹ̀, kí àwọn ẹranko sì pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo gba gbogbo ilẹ̀ náà mọ́ yín lọ́wọ́.