5. n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi,ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ.Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.
6. “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,
7. n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”
8. OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé,“N óo tún kó àwọn mìíràn jọ,kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”
9. Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀,gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun.