1. Ní ọjọ́ wọ̀n-un-nì, Jòhánù onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní ihà Jùdíà.
2. Ó ń wí pé, “Ẹ ronú pìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run dé tán.”
3. Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Àìsáyà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé:“Ohùn ẹnìkan ti ń kígbe ní ihà,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,ẹ se ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”