1. Jésù tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé:
2. “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àṣè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin.
3. Ó rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti lọ sọ fún àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ pé àsìkò ti tó láti wá sí ibi àsè. Ṣùgbọ́n gbogbo wọn kọ̀ láti wá.
4. “Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti se àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyáwó.’