9. Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.”
10. Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ,ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’
11. Lóòótọ̀ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Jòhánù onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀ jù ú lọ.
12. Láti ìgbà ọjọ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di àfagbárawọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.
13. Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó wí tẹ́lẹ̀ kí Jòhánù kí ó tó dé.
14. Bí ẹ̀yin yóò bá gbà á, èyí ni Èlíjà tó ń bọ̀ wá.
15. Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́
16. “Kí ni èmi ìbá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọ kékéré tí ń jókòó ní ọjà tí wọ́n sì ń ké pe àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn: