25. Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jésù, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ Jésù.
26. Gíríkì ní obìnrin náà, Ṣíríàfonísíà ní orílẹ̀ èdè rẹ̀. Ó bẹ Jésù kí ó bá òun lé ẹ̀mí Èsù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.
27. Jésù sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
28. Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábílì.”
29. “Ó sì wi fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”
30. Nígbà tí ó náà padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.
31. Nígbà náà ni Jésù fi agbégbé Tírè àti Ṣídónì sílẹ̀, ó wá si òkun Gálílì láàrin agbègbè Dékápólì.
32. Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, àwọn ènìyàn sì bẹ Jésù pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e.
33. Jésù sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ sọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀.
34. Nígbà náà ni Jésù wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Éfátà,” èyí ni, “Ìwọ ṣí.”