10. “Olubùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dáfídì, baba wa!”“Hòsánà lókè ọ̀run!”
11. Jésù wọ Jerúsálémù ó sì lọ sí inú tẹ́ḿpílì. Ó wo ohun gbogbo yíká fínnífínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti sú. Ó padà lọ sí Bẹ́tanì pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.
12. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Bẹ́tanì, ebi ń pa Jésù.
13. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán ti ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so.
14. Lẹ́yìn náà, Jésù pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.
15. Nígbà ti wọ́n padà sí Jerúsálémù, ó wọ inú tẹ́ḿpílì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹ́ḿpílì ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀.
16. Kò sì gba ẹnikẹ́ni láàyè láti gbé ẹrù ọjà títa wọlé.