Nígbà tí Hẹ́rọ́dù, sì rí Jésù, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ ó sáà ti ń gbọ́ ìhìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.