4. Jóṣéfù pẹ̀lú sì gòkè láti Násárẹ́tì ìlú Gálílì, sí ìlú Dáfídì ní Jùdéà, tí à ń pè ní Bétílẹ́hẹ́mù; nítorí ti ìran àti ìdílé Dáfídì ní í ṣe,
5. Láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Màríà aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ tí tó bi.
6. Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun óò bí.
7. Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí àyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.
8. Àwọn olùsọ́-àgùntàn ńbẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń sọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.
9. Ańgẹ́lì Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
10. Ańgẹ́lì náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìn rere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.
11. Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónì-ín ní ìlú Dáfídì, tí í ṣe Kírísítì Olúwa.
12. Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ-ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.
13. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ Ańgẹ́lì náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,
14. “Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run,Àti ní ayé àlààáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”