8. Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Jópà. A fi ran hàn Pétérù pẹ̀lú.
9. Ni ijọ́ kéjì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Pétérù gun òkè ilé lọ gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́:
10. Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran.
11. Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun-èlò kan si sọ̀kálẹ̀ bí gọ̀gọ̀wú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀:
12. Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹrankọ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, ati ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run.
13. Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Pétérù; máa pa kí o sì má a jẹ.”
14. Ṣùgbọn Pétérù dáhùn pé, “Àgbẹdọ̀, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ ati aláìmọ́ kan rí.”
15. Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ́méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀ nù, ìwọ má ṣe pè é léèwọ̀ mọ́.”
16. Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.
17. Bí Pétérù sì ti ń dààmù nínú ara rẹ̀ bí a ìbá ti mọ̀ ìran tí oun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Kọ̀nélíù dé. Wọ́n ń bèèrè ilé Símónì, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà.
18. Wọn nahùn ń bèèrè bí Símónì tí a ń pè ní Pétérù, wọ̀ níbẹ̀.
19. Bí Pétérù sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ.
20. Njẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kọminú ohunkohun: nítorí èmi ni ó rán wọn.”
21. Nígbà náà ni Pétérù sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí tẹ̀ ti ẹ fi wá?”
22. Wọ́n sì wí pé, “Kọ̀nẹ́líù balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ́ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ ańgẹ́lì mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”
23. Nígbà náà ni ó pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.Níjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, nínú àwọn arákùnrin ní Jopa sì bá a lọ pẹ̀lú.
24. Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesaríà, Kọ̀nélíù sì ti ń rétí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ.
25. Ó sì ṣe bí Pétérù ti ń wọlé, Kọ̀nélíù pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un.
26. Ṣùgbọ́n Pétérù gbé e dìde, ó ni, “Dìde; ènìyàn ni èmi tìkárami pẹ̀lú.”