6. Ó wọ̀ sí ilé Símónì aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”
7. Nígbà tí ańgẹ́lì náà tí ó bá Kọ̀nélíù sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, ati ọmọ ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo.
8. Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Jópà. A fi ran hàn Pétérù pẹ̀lú.
9. Ni ijọ́ kéjì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Pétérù gun òkè ilé lọ gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́:
10. Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran.
11. Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun-èlò kan si sọ̀kálẹ̀ bí gọ̀gọ̀wú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀:
12. Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹrankọ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, ati ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run.
13. Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Pétérù; máa pa kí o sì má a jẹ.”
14. Ṣùgbọn Pétérù dáhùn pé, “Àgbẹdọ̀, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ ati aláìmọ́ kan rí.”
15. Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ́méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀ nù, ìwọ má ṣe pè é léèwọ̀ mọ́.”
16. Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.
17. Bí Pétérù sì ti ń dààmù nínú ara rẹ̀ bí a ìbá ti mọ̀ ìran tí oun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Kọ̀nélíù dé. Wọ́n ń bèèrè ilé Símónì, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà.
18. Wọn nahùn ń bèèrè bí Símónì tí a ń pè ní Pétérù, wọ̀ níbẹ̀.
19. Bí Pétérù sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ.
20. Njẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kọminú ohunkohun: nítorí èmi ni ó rán wọn.”
21. Nígbà náà ni Pétérù sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí tẹ̀ ti ẹ fi wá?”