18. Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìléera àti àìlérè rẹ̀.
19. (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.
20. Níwọ̀n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni.
21. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, ṣùgbọ́n ti òún jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nípa ẹni tí ó wí fún un pé,“Olúwa búra,kí yóò sì yí padà:‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì.’ ”
22. Níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni Jésù ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.
23. Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú.
24. Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ nípò.