1. Ǹjẹ́ bí Kírísítì ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀;
2. Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run.
3. Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rìnrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra.
4. Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejú ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.
5. Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú.
6. Nítorí èyí ní a ṣá ṣe wàásù ìyìn rere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láàyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.
7. Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa sọra nínú àdúrà.
8. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrin ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.
9. Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú.