Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láì ṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kansoso ní ń bẹ, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo.