37. Má a kíyèsí ẹni pípé,kí o sì wo adúró ṣinṣin,nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38. Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjání a ó parun papọ̀;ìran àwọn ènìyàn búburúní a ó gé kúrò.
39. Ìgbàlà àwọn adúró ṣinṣinwa láti ọ̀dọ̀ Olúwa:òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40. Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́yóò sì gbà wọ́n;yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú,yóò sì gbà wọ́n là,nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.