25. Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;nígbà tí wọn wò mí, wọn gbọn orí wọn.
26. Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ.
27. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ Rẹ ni èyíwí pé ìwọ, Olúwa, ni o ṣe é.
28. Wọ́n o máa gégùn-ún, ṣùgbọ́n ìwọ má súré;Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ yóò yọ̀
29. Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjúkí á sì fi ìdàrú dàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.
30. Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yìn Olúwa gidigidiní àárin ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín
31. Nítorí ó dúró ni apá ọ̀tún aláìníláti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn Rẹ̀ lẹ́bi.