10. Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀,ó múra bí aṣẹ́wó pẹ̀lú ètè búburú.
11. (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí,ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
12. bí ó ti ń já níhìn ín ní ó ń já lọ́hùn úngbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
13. Ó dìí mú, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnupẹ̀lú ojú dídín ó wí pé:
14. “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
15. Nítorí náà ni mo ṣe jáde wá pádé è rẹ;mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
16. Mo ti tẹ́ ibùṣùn mipẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Éjíbítì.
17. Mo ti fi nǹkan Olóòórùn dídùn sí ibùṣùn mibí i míra, álóè àti kínámónì.
18. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
19. Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;ó ti lọ sí ìrìnàjò jínjìn.