15. Ọ̀lẹ ṣíṣẹ́ máa ń fa oorun sísùn fọnfọnfọnebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
16. Ẹni-kẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
17. Ẹni tí ó ṣáànú talákà, Olúwa ní ó yáyóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
18. Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú iparun un rẹ̀.
19. Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀bí ìwọ bá gbàá là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan síi.
20. Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
21. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyànṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.
22. Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;ó sàn láti jẹ́ talákà ju òpùrọ́ lọ.
23. Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá:nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láì sí ewu.
24. Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
25. Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ síi.
26. Ẹni tí ó já baba rẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jádeó jẹ́ adójútini ọmọ.