6. Ọmọ-Ọmọ ni adé orí arúgbóòbí sì ni ìyangàn àwọn ọmọ.
7. Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aláìgbọ́n, mélòómélòó ni ètè tí ń parọ́ fún àwọn alákóso!
8. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ oògùn fún ẹni tí ó ń fún ni ohungbogbo, ibikíbi tí ó bá tẹ̀ sí ni ó ń yege.
9. Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì níyà.
10. Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun ènìyàn olóyeju ọgọ́rùn ún pàsán lẹ́yìn aláìgbọ́n.
11. Oríkunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
12. Ó sàn kí ènìyàn pàdé béárì tí a ti kó lọ́mọjù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
13. Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ire,ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
14. Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún ominítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
15. Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kóríra méjèèjì.
16. Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrèníwọ̀n bí kò ti ní èròńgbà láti rí ọgbọ́n?
17. Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,Arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.