Wọ́n sì sá níwáju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀.