23. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ ọ̀rá mààlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́
24. Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko ìgbẹ́ pa, fún nǹkan mìíràn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.
25. Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rúbọ sísun sí Olúwa ni ẹ gbọdọ̀ gé kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.
26. Ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tàbí ẹran ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé.
27. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀, a ó ge ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”
28. Olúwa sọ fún Mósè pé:
29. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa.
30. Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún Olúwa, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú Olúwa bí ọrẹ fífí.
31. Àlùfáà yóò sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ ṣùgbọ́n igẹ̀ ẹran náà jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀,
32. kí ẹ fún àlùfáà ní itan ọ̀tún lára ọrẹ àlàáfíà yín gẹ́gẹ́ bí ìpín tiyín fún àlùfáà.
33. Ọmọ Árónì ẹni tí ó rúbọ ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà ni kí ó ni itan ọ̀tún gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.
34. Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Árónì àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Ísírẹ́lì.’ ”