1. Ìpín ti Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò, ó sì la aṣálẹ̀ kọjá láti ibẹ̀ sí ọ̀nà ihà sí òkè ìlú Bẹ́tẹ́lì.
2. Ó sì tẹ̀ṣíwájú láti Bẹ́tẹ́lì (tí í ṣe Lúsì) kọjá lọ sí agbègbè àwọn ará Áríkì ní Atárótù,
3. Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn agbègbè àwọn ará Jéfílétì, títí dé ilẹ̀ ìṣàlẹ̀ Bẹti Hórónì, àní dé Gésérì, ó sì parí sí etí òkun.
4. Báyìí ni Mànásè àti Éfúráímù, àwọn ọmọ Jósẹ́fù gba ilẹ̀ ìní wọn.
5. Èyí ni ilẹ̀ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé:Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Ádárì ní ìlà oòrùn lọ sí Okè Bẹti-Hórónì.