16. “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó sì dè ọ lọ látiinú ìhágágá síbi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálànínú rẹ̀ ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ a jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.
17. Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọnbúburú; ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
18. Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹmáa bàà tàn ọ́; láti jẹ́ kí títóbi èyà mú ọ sìnà.
19. Ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fidé bá ọ bí? Tàbi ipa agbára rẹ?
20. Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń kéàwọn orilẹ̀ èdè kúrò ní ipò wọn.
21. Máa sọra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀padà sí búrubú; Nítori èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.
22. “Kíyèsí i, Ọlọ́run á gbé-ni-ga nípaagbára rẹ̀; ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí òun?
23. Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?