1. “Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àtiibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.
2. Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin,bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.
3. Ènìyàn ni ó parí òkùnkùn, ó sì ṣeàwárí òkúta òkùnkùn àti tiinú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.
4. Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jìn sí àwọn tíń gbé òkè, àwọn tí ẹṣẹ̀ ènìyàngbàgbé; wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.
5. Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá,àti ohun tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni ó yí sókè bí ẹni pé iná.
6. Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Sáfírì, o sìní erùpẹ̀ wúrà.
7. Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojúgúnnugún kò rí i rí;