Ísíkẹ́lì 44:5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Olúwa sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáadáa, fetí sílẹ̀ dáadáa kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa ofin lórí ilé Olúwa náà. Fiyèsí ẹnu ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́.