1. Olúwa sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé:
2. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì, jáde ni oko ẹrú.
3. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
4. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara rẹ ní àwòrán ohun kóhun tí ń bẹ ní òkè ọ̀run tàbí tí ń bẹ ní ayé, tàbí tí ń bẹ ní ìṣàlẹ̀ omi.