12. Ṣùgbọ́n Áhásì sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán Olúwa wò.”
13. Lẹ́yìn náà Àìṣáyà sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsìnyí, ìwọ ilé Dáfídì, kò ha tọ́ láti tan ènìyàn ní ṣùúrù, o ó ha tan Ọlọ́run ní ṣùúrù bí?
14. Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.
15. Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan àre.
16. Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan àre, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.
17. Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Éfáímù ti yà kúrò ní Júdà, yóò sì mú ọba Áṣíríà wá.”