3. Èmi sọ àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́,ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mímọ̀;Lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbéṣẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.
4. Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó;àwọn iṣan ọrùn un yín irin ni wọ́n;iwájúu yín idẹ ni
5. Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́ sí i.’
6. Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọnǸjẹ́ o kò ní gbà wọ́n bí?“Láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi yóò máa sọfún ọ nípa nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó farasin tí ìwọ kò mọ̀.
7. A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’
8. Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bíláti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.
9. Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;nítorí ìyìn ara mi, mo fà á ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,kí a má ba à ké ọ kúrò.
10. Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pékì í ṣe bí i fàdákà;Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.
11. Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyíBáwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràn.
12. “Tẹ́tí sí mi, Ìwọ Jákọ́bùÍsírẹ́lì ẹni tí mo pè:Èmi ni ẹni náà;Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
13. Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀,àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;nígbà tí mo pè wọ́n,gbogbo wọn dìde ṣókè papọ̀.
14. “Ẹ gbárajọ pọ̀ gbogbo yín kí ẹ sì dẹtí:Èwo nínú àwọn ère òrìṣà rẹló ti sọ nǹkan wọ̀nyí?Àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ Olúwani yóò gbé ète yìí jáde sí Bábílónì;apá rẹ̀ ni yóò dojú kọ àwọn aráa Bábílónì.
15. Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.Èmi yóò mú un wá,òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.