6. Ní ọjọ́ iwájú Jákọ́bù yóò ta gbòǹgbò,Ísírẹ́lì yóò tanná yóò sì rudièṣo rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
7. Ǹjẹ́ Olúwa ti lù úgẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?Ǹjẹ́ a ti pa ágẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?
8. Nípa ogun-jíjà àti lílé nílùú ni ófi dojú kọ ọ́pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà oorùn fẹ́
9. Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wàfún ẹ̀ṣẹ̀ Jákọ́bù,èyí ni yóò sì jẹ́ èṣo kíkún tiìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ:Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹdàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,kì yóò sí ọ̀pá Áṣérà tàbí pẹpẹ tùràrítí yóò wà ní ìdúró.
10. Ìlú olódi náà ti dahoro,ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀tìgẹ́gẹ́ bí aṣálẹ̀;níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹkoníbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.
11. Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ gbẹ, a kán wọn dànùàwọn obìnrin wá wọ́n, sì fi wọ́n dánánítorí àwọn ènìyàn tí òye kò yéni wọ́n jẹ́;Nítorí náà ni Ẹlẹ́dàá wọn kò ṣe yọ́nú sí wọn.Ẹlẹ́dàá wọn kò sì síjú àánú wò wọ́n.