Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Éjíbítì lọ sí Ásíríà. Àwọn ará Ásíríà yóò lọ sí Éjíbítì àti àwọn ará Éjíbítì lọ sí Ásíríà. Àwọn ará Éjíbítì àti ará Ásíríà yóò jọ́sìn papọ̀.