Ilẹ̀ Júdà yóò da wárìwàrì jó àwọn ará Éjíbítì; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Júdà létíi wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbérò láti ṣe sí wọn.